Eksodu 32:24
Exodus 32:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní òrùka wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Nígbà náà ni wọ́n fún mi ní wúrà, mo sì jù ú sínú iná, a sì fi ṣe ẹgbọrọ màlúù yìí!”
Exodus 32:24 in English
Exodus 32:24 · Berean Standard Bible
So I said to them, ‘Whoever has gold, let him take it off,’ and they gave it to me. And when I threw it into the fire, out came this calf!”
Context
22Aaroni dáhùn wí pé, “Má ṣe bínú olúwa mi. Ìwọ mọ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe burú tó. 23Wọ́n sọ fún mi pé, ‘Ṣe òrìṣà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa. Bí ó ṣe ti Mose ẹni tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá àwa kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.’ 24Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní òrùka wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Nígbà náà ni wọ́n fún mi ní wúrà, mo sì jù ú sínú iná, a sì fi ṣe ẹgbọrọ màlúù yìí!” 25Mose rí pé àwọn ènìyàn náà kò ṣe ṣàkóso àti pé Aaroni ti sọ wọ́n di aláìlákóṣo láàrín àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn. 26Bẹ́ẹ̀ ni Mose dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún Olúwa, kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ará Lefi sì péjọ yí i ká.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.