Eksodu 32:21
Exodus 32:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose sọ fún Aaroni pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe sí ọ, tí ìwọ ṣe mú wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí?”
Exodus 32:21 in English
Exodus 32:21 · Berean Standard Bible
“What did this people do to you,” Moses asked Aaron, “that you have led them into so great a sin?”
Context
19Nígbà tí Mose dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì sọ wàláà ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ ní ìsàlẹ̀ òkè náà. 20Ó sì gbé ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n ṣe, ó sì fi iná jó wọn; ó sì lọ̀ wọ́n kúnná, ó dà á sínú omi, ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli mu ún. 21Mose sọ fún Aaroni pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe sí ọ, tí ìwọ ṣe mú wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí?” 22Aaroni dáhùn wí pé, “Má ṣe bínú olúwa mi. Ìwọ mọ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe burú tó. 23Wọ́n sọ fún mi pé, ‘Ṣe òrìṣà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa. Bí ó ṣe ti Mose ẹni tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá àwa kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.