Native Bible

Exodus 31:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

láti gbẹ́ òkúta àti láti tò wọ́n, láti ṣiṣẹ́ ní igi, àti láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà.

Exodus 31:5 in English

Exodus 31:5 · Berean Standard Bible

to cut gemstones for settings, and to carve wood, so that he may be a master of every craft.

Context

3Èmi sì ti fi Ẹ̀mí Ọlọ́run kún un pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 4Láti ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní wúrà, fàdákà àti idẹ, 5láti gbẹ́ òkúta àti láti tò wọ́n, láti ṣiṣẹ́ ní igi, àti láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 6Síwájú sí i, èmi ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, láti ràn án lọ́wọ́. “Bákan náà, Èmi ti fi ọgbọ́n fún gbogbo àwọn oníṣẹ́-ọnà láti ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún ọ: 7“àgọ́ àjọ náà, àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò àgọ́ náà,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.