Native Bible

Exodus 31:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a yóò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a yóò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ.

Exodus 31:14 in English

Exodus 31:14 · Berean Standard Bible

Keep the Sabbath, for it is holy to you. Anyone who profanes it must surely be put to death. Whoever does any work on that day must be cut off from among his people.

Context

12Olúwa wí fún Mose pé, 13“Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́. 14“ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a yóò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a yóò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ. 15Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ́. 16Nítorí náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóò ṣe máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíran tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mú títí láé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.