Native Bible

Exodus 3:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Àwọn àgbàgbà Israẹli yóò fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ. Nígbà náà ni ìwọ, àti àwọn àgbàgbà yóò jọ tọ ọba Ejibiti lọ, ẹ ó sì wí fún un pé, ‘Olúwa, Ọlọ́run àwọn ará Heberu ti pàdé wa. Jẹ́ kí a lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú aginjù láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run.’

Exodus 3:18 in English

Exodus 3:18 · Berean Standard Bible

The elders of Israel will listen to what you say, and you must go with them to the king of Egypt and tell him, ‘The LORD, the God of the Hebrews, has met with us. Now please let us take a three-day journey into the wilderness, so that we may sacrifice to the LORD our God.’

Context

16“Lọ, kó àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín, Ọlọ́run Abrahamu, ti Isaaki, àti ti Jakọbu; ni ó farahàn mi, ó sì wí pé, lóòótọ́ èmi ti ń bojú wò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Ejibiti. 17Èmi sì ti ṣe ìlérí láti mú un yín jáde kúrò nínú ìpọ́njú yín ni ilẹ̀ Ejibiti wá sí ilẹ̀ Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi; ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.’ 18“Àwọn àgbàgbà Israẹli yóò fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ. Nígbà náà ni ìwọ, àti àwọn àgbàgbà yóò jọ tọ ọba Ejibiti lọ, ẹ ó sì wí fún un pé, ‘Olúwa, Ọlọ́run àwọn ará Heberu ti pàdé wa. Jẹ́ kí a lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú aginjù láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run.’ 19Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ọba Ejibiti kò ní jẹ́ kí ẹ lọ bí kò ṣe pé ọwọ́ ńlá Ọlọ́run wà ni ara rẹ̀. 20Nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mí láti lu àwọn ará Ejibiti pẹ̀lú gbogbo ohun ìyanu tí èmi yóò ṣe ni àárín wọn. Lẹ́yìn náà, òun yóò jẹ́ kí ẹ máa lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.