Native Bible

Exodus 29:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ yóò sì mú igẹ̀ àgbò ìyàsímímọ́ Aaroni, ìwọ yóò si fí ì ni ẹbọ fífì níwájú Olúwa; ìpín tìrẹ ni èyí.

Exodus 29:26 in English

Exodus 29:26 · Berean Standard Bible

Take the breast of the ram of Aaron’s ordination and wave it before the LORD as a wave offering, and it will be your portion.

Context

24Ìwọ yóò fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa. 25Nígbà náà ni ìwọ yóò sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹ̀lú ẹbọ sísun fún òórùn dídùn níwájú Olúwa, ẹbọ ti a fi iná sun sí Olúwa. 26Ìwọ yóò sì mú igẹ̀ àgbò ìyàsímímọ́ Aaroni, ìwọ yóò si fí ì ni ẹbọ fífì níwájú Olúwa; ìpín tìrẹ ni èyí. 27“Ìwọ yóò sì ya igẹ̀ ẹbọ fífì náà sí mímọ́, àti ìtàn ẹbọ à gbé sọ sókè tí a fì, tí a sì gbé sọ sókè nínú àgbò ìyàsímímọ́ náà, àní nínú èyí tí í ṣe Aaroni àti nínú èyí tí ì ṣe tí àwọn ọmọ rẹ̀. 28Èyí ni yóò sì máa ṣe ìpín ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli nígbà gbogbo. Nítorí ẹbọ à gbé sọ sókè ni ẹbọ tí yóò ṣì ṣe èyí ni ẹbọ tí àwọn ọmọ Israẹli yóò máa ṣe sí Olúwa láti inú ẹbọ àlàáfíà wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.