Eksodu 29:21
Exodus 29:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ àti nínú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì wọ́n ọn sára Aaroni àti sára aṣọ rẹ̀, sára àwọn ọmọ rẹ àti sára aṣọ wọn. Nígbà náà ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn yóò di mímọ́.
Exodus 29:21 in English
Exodus 29:21 · Berean Standard Bible
And take some of the blood on the altar and some of the anointing oil and sprinkle it on Aaron and his garments, as well as on his sons and their garments. Then he and his garments will be consecrated, as well as his sons and their garments.
Context
19“Ìwọ yóò mú àgbò kejì, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí. 20Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. Ìwọ yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n pẹpẹ náà yíká. 21Ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ àti nínú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì wọ́n ọn sára Aaroni àti sára aṣọ rẹ̀, sára àwọn ọmọ rẹ àti sára aṣọ wọn. Nígbà náà ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn yóò di mímọ́. 22“Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún. (Èyí ni àgbò fún ìyàsímímọ́.) 23Láti inú apẹ̀rẹ̀ ìṣù àkàrà aláìwú, èyí tí ó wà níwájú Olúwa, mú ìṣù kan, àkàrà tí a fi òróró dín àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.