Native Bible

Exodus 29:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ìwọ yóò sun àgbò náà lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni sí Olúwa, olóòórùn dídùn ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe sí Olúwa ni.

Exodus 29:18 in English

Exodus 29:18 · Berean Standard Bible

Then burn the entire ram on the altar; it is a burnt offering to the LORD, a pleasing aroma, an offering made by fire to the LORD.

Context

16Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì fi wọ́n pẹpẹ náà yíká. 17Ìwọ yóò sì gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ìwọ yóò sì fọ inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tò wọ́n pẹ̀lú orí rẹ̀ lé ara wọn. 18Nígbà náà ni ìwọ yóò sun àgbò náà lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni sí Olúwa, olóòórùn dídùn ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe sí Olúwa ni. 19“Ìwọ yóò mú àgbò kejì, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí. 20Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. Ìwọ yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n pẹpẹ náà yíká.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.