Eksodu 28:38
Exodus 28:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ó wà níwájú orí Aaroni, kí ó sì lè máa ru ẹ̀bi tí ó jẹ mọ́ ẹ̀bùn mímọ́ ti àwọn ọmọ Israẹli ti yà sí mímọ́, èyíkéyìí tí ẹ̀bùn wọn lè jẹ́. Yóò máa wà níwájú orí Aaroni nígbà gbogbo, kí wọn lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.
Exodus 28:38 in English
Exodus 28:38 · Berean Standard Bible
And it will be worn on Aaron’s forehead, so that he may bear the iniquity of the holy things that the sons of Israel consecrate with regard to all their holy gifts. It shall always be on his forehead, so that they may be acceptable before the LORD.
Context
36“Ìwọ yóò sì ṣe àwo kìkì wúrà, ìwọ yóò sì fín sára rẹ̀ bí, fínfín èdìdì àmì pé.
Mímọ́ sí Olúwa. 37Ìwọ yóò fi ọ̀já aláró sára rẹ̀ ìwọ yóò sì so ó mọ́ fìlà náà; kí ó sì wà níwájú fìlà náà. 38Kí ó wà níwájú orí Aaroni, kí ó sì lè máa ru ẹ̀bi tí ó jẹ mọ́ ẹ̀bùn mímọ́ ti àwọn ọmọ Israẹli ti yà sí mímọ́, èyíkéyìí tí ẹ̀bùn wọn lè jẹ́. Yóò máa wà níwájú orí Aaroni nígbà gbogbo, kí wọn lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa. 39“Ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára hun ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára ṣe fìlà. Ìwọ yóò sì fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe ọ̀já àmùrè. 40Ìwọ yóò sì dá ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ọ̀já àmùrè àti ìgbàrí fún àwọn ọmọ Aaroni, láti fún wọn ní ọ̀ṣọ́ àti ọlá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.