Native Bible

Exodus 28:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ yóò sì so wọ́n pọ̀ mọ́ èjìká efodu náà ní òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli. Aaroni yóò sì máa ní orúkọ wọn níwájú Olúwa ní èjìká rẹ̀ méjèèjì fún ìrántí.

Exodus 28:12 in English

Exodus 28:12 · Berean Standard Bible

Fasten both stones on the shoulder pieces of the ephod as memorial stones for the sons of Israel. Aaron is to bear their names on his two shoulders as a memorial before the LORD.

Context

10Ní ti ìbí wọn, orúkọ àwọn mẹ́fà sára òkúta kan àti orúkọ àwọn mẹ́fà tókù sára òkúta kejì. 11Iṣẹ́ ọnà òkúta fínfín, bí ìfín èdìdì àmì, ni ìwọ yóò fún òkúta méjèèjì gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ọmọ Israẹli: ìwọ yóò sì dè wọ́n sí ojú ìdè wúrà. 12Ìwọ yóò sì so wọ́n pọ̀ mọ́ èjìká efodu náà ní òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli. Aaroni yóò sì máa ní orúkọ wọn níwájú Olúwa ní èjìká rẹ̀ méjèèjì fún ìrántí. 13Ìwọ yóò sì ṣe ojú ìdè wúrà, 14àti okùn ẹ̀wọ̀n méjì ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè kí o sì so ẹ̀wọ̀n náà mọ́ ojú ìdè náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.