Native Bible

Exodus 28:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ìwọ sì mú Aaroni arákùnrin rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, mú un kúrò ni àárín àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ Nadabu, Abihu, Eleasari, àti Itamari, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

Exodus 28:1 in English

Exodus 28:1 · Berean Standard Bible

“Next, have your brother Aaron brought to you from among the Israelites, along with his sons Nadab, Abihu, Eleazar, and Ithamar, to serve Me as priests.

Context

1“Ìwọ sì mú Aaroni arákùnrin rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, mú un kúrò ni àárín àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ Nadabu, Abihu, Eleasari, àti Itamari, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. 2Ìwọ yóò sì dá aṣọ mímọ́ fún Aaroni arákùnrin rẹ, láti fún un ni ọ̀ṣọ́ àti ọlá. 3Ìwọ yóò sì sọ fún gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, àwọn ẹni tí mo fún ní ọgbọ́n, kí wọn kí ó lè dá aṣọ fún Aaroni, fún ìyàsímímọ́ rẹ̀, kí ó lè ba à sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.