Eksodu 27:5
Exodus 27:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbé e sí abẹ́ igun pẹpẹ náà, kí ó lè dé ìdajì pẹpẹ náà.
Exodus 27:5 in English
Exodus 27:5 · Berean Standard Bible
Set the grate beneath the ledge of the altar, so that the mesh comes halfway up the altar.
Context
3Ìwọ yóò sì ṣe abọ́ ìtẹ́dìí rẹ láti máa gba eérú rẹ̀, àti ọkọ̀ rẹ̀, àwokòtò rẹ̀, àti fọ́ọ̀kì ẹran rẹ̀, àti àwo iná rẹ̀, gbogbo ohun èlò rẹ̀ ni ìwọ yóò fi idẹ ṣe. 4Ìwọ yóò sí ṣe ni wẹ́wẹ́, iṣẹ́ àwọ̀n idẹ, kí o sì ṣe òrùka idẹ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin iṣẹ́ àwọ̀n náà. 5Gbé e sí abẹ́ igun pẹpẹ náà, kí ó lè dé ìdajì pẹpẹ náà. 6Ìwọ yóò sí ṣe òpó igi kasia fún pẹpẹ náà, kí o sì bò ó pẹ̀lú idẹ. 7A ó sì bọ àwọn òpó náà ní òrùka, wọn yóò sì wà ní ìhà méjèèjì pẹpẹ nígbà tí a bá rù ú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.