Eksodu 27:19
Exodus 27:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo irú iṣẹ́ tí ó wà kí ó ṣe, papọ̀ pẹ̀lú gbogbo èèkàn àgọ́ náà àti fún tí àgbàlá náà, kí ó jẹ́ idẹ.
Exodus 27:19 in English
Exodus 27:19 · Berean Standard Bible
All the utensils of the tabernacle for every use, including all its tent pegs and the tent pegs of the courtyard, shall be made of bronze.
Context
17Gbogbo òpó ti ó wà ní àyíká àgbàlá náà ni a ó fi fàdákà ṣo pọ̀ àti ìkọ́, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ. 18Àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ni gíga àti mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, pẹ̀lú aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn mita méjì ní gíga, àti pẹ̀lú ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ. 19Gbogbo irú iṣẹ́ tí ó wà kí ó ṣe, papọ̀ pẹ̀lú gbogbo èèkàn àgọ́ náà àti fún tí àgbàlá náà, kí ó jẹ́ idẹ. 20“Ìwọ yóò sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn kí ó mú òróró olifi dáradára tí a gún fún ọ wá, fún ìmọ́lẹ̀, kí fìtílà lè máa tàn síbẹ̀. 21Ní àgọ́ àjọ, lẹ́yìn òde aṣọ ìkélé tí ó wá níwájú ẹ̀rí náà, Aaroni àti òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, ni yóò tọ́jú rẹ̀ láti alẹ́, títí di òwúrọ̀ níwájú Olúwa: yóò sì di ìlànà láéláé ni ìrandíran wọn lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.