Native Bible

Exodus 26:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ṣe àádọ́ta ìkọ́ idẹ kí o sì kó wọn sínú ọ̀jábó láti fi so àgọ́ náà pọ̀ kí ó lè jẹ́ ọ̀kan.

Exodus 26:11 in English

Exodus 26:11 · Berean Standard Bible

Make fifty bronze clasps and put them through the loops to join the tent together as a unit.

Context

9Ìwọ ó so aṣọ títa márùn-ún pọ̀ mọ́ ara wọn se ọ̀kan, ó sì tún so mẹ́fà tókù mọ́ ara wọn se ọ̀kan. Ìwọ ó sì ṣẹ́ aṣọ títa kẹfà po sí méjì níwájú àgọ́ náà. 10Ìwọ ó sì pa àádọ́ta ajábó sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kan, wọ́n sì tún pa ajábó mìíràn sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kejì. 11Nígbà náà ṣe àádọ́ta ìkọ́ idẹ kí o sì kó wọn sínú ọ̀jábó láti fi so àgọ́ náà pọ̀ kí ó lè jẹ́ ọ̀kan. 12Àti ìyókù tí ó kù nínú aṣọ títa àgọ́ náà, ìdajì aṣọ títa tí ó kù, yóò rọ̀ sórí ẹ̀yìn àgọ́ náà. 13Aṣọ títa àgọ́ náà yóò jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan gígùn ní ìhà méjèèjì, èyí tí ó kù yóò rọ̀ sórí ìhà àgọ́ náà láti fi bò ó.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.