Native Bible

Exodus 25:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ ó sì ṣe kérúbù méjì láti inú wúrà tí a fi òòlù sí igun ìtẹ́ àánú náà.

Exodus 25:18 in English

Exodus 25:18 · Berean Standard Bible

Make two cherubim of hammered gold at the ends of the mercy seat,

Context

16Nígbà náà ni ìwọ yóò fi ẹ̀rí ti èmi yóò fi fún ọ sínú àpótí náà. 17“Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní fífẹ̀. 18Ìwọ ó sì ṣe kérúbù méjì láti inú wúrà tí a fi òòlù sí igun ìtẹ́ àánú náà. 19Ìwọ ó ṣe kérúbù kan sí igun kìn-ín-ní àti kérúbù kejì sí igun kejì, kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì pẹ̀lú ìbòrí wọn. 20Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè, tí wọn yóò sì fi ìyẹ́ apá wọn ṣe ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú. Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.