Eksodu 24:7
Exodus 24:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí Olúwa wí. Àwa yóò sì gbọ́rọ̀.”
Exodus 24:7 in English
Exodus 24:7 · Berean Standard Bible
Then he took the Book of the Covenant and read it to the people, who replied, “All that the LORD has spoken we will do, and we will be obedient.”
Context
5Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si Olúwa. 6Mose bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ. 7Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí Olúwa wí. Àwa yóò sì gbọ́rọ̀.” 8Nígbà náà ni Mose gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Olúwa ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.” 9Mose àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin àwọn àgbàgbà Israẹli gòkè lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.