Native Bible

Exodus 23:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò rán oyin ṣáájú rẹ láti lé àwọn ará: Hifi, Kenaani àti Hiti kúrò ni ọ̀nà rẹ.

Exodus 23:28 in English

Exodus 23:28 · Berean Standard Bible

I will send the hornet before you to drive the Hivites and Canaanites and Hittites out of your way.

Context

26Oyún kò ní bàjẹ́ lára obìnrin kan, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan kì yóò yàgàn ni ilẹ̀ rẹ. Èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn. 27“Èmi yóò rán ẹ̀rù mi lọ ṣáájú rẹ, ìdàrúdàpọ̀ yóò sì wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ bá da ojú kọ. Èmi yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ yí ẹ̀yìn padà sí ọ, kí wọn sì sá ní iwájú rẹ. 28Èmi yóò rán oyin ṣáájú rẹ láti lé àwọn ará: Hifi, Kenaani àti Hiti kúrò ni ọ̀nà rẹ. 29Ṣùgbọ́n, Èmi kò ni lé gbogbo wọn jáde ni ọdún kan ṣoṣo, ki ilẹ̀ náà má ba à di ahoro, àwọn ẹranko búburú yóò sì ti pọ̀jù fún ọ. 30Díẹ̀díẹ̀ ni èmi yóò máa lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ, títí ìwọ yóò fi pọ̀ tó láti gba gbogbo ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ìní.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.