Eksodu 23:25
Exodus 23:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin yóò sí máa sin Olúwa Ọlọ́run yin, òun yóò si bùsi oúnjẹ rẹ. Èmi yóò mú àìsàn kúrò láàrín rẹ.
Exodus 23:25 in English
Exodus 23:25 · Berean Standard Bible
So you shall serve the LORD your God, and He will bless * your bread and your water. And I will take away sickness from among you.
Context
23Angẹli mi yóò lọ níwájú rẹ, yóò sì mú ọ dé ọ̀dọ̀ àwọn ará: Amori, Hiti, Peresi, Kenaani, Hifi àti Jebusi, èmi a sì gé wọn kúrò. 24Ìwọ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún òrìṣà wọn, bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, tàbí kí ẹ tẹ̀lé ìṣe wọn. Kí ìwọ kí ó si wó wọn lulẹ̀, kí ìwọ kí ó sì fọ́ ère òkúta wọ́n túútúú. 25Ẹ̀yin yóò sí máa sin Olúwa Ọlọ́run yin, òun yóò si bùsi oúnjẹ rẹ. Èmi yóò mú àìsàn kúrò láàrín rẹ. 26Oyún kò ní bàjẹ́ lára obìnrin kan, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan kì yóò yàgàn ni ilẹ̀ rẹ. Èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn. 27“Èmi yóò rán ẹ̀rù mi lọ ṣáájú rẹ, ìdàrúdàpọ̀ yóò sì wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ bá da ojú kọ. Èmi yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ yí ẹ̀yìn padà sí ọ, kí wọn sì sá ní iwájú rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.