Eksodu 22:9
Exodus 22:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ẹnìkan bá ni akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, aṣọ tàbí ohun ìní mìíràn tí ó sọnù ní ọ̀nà ti kò bá òfin mu, tí a sì rí ẹni ti ó sọ pé òun ni ó ní ín, àwọn méjèèjì yóò mú ẹjọ́ wọn wá sí iwájú adájọ́. Ẹnikẹ́ni tí adájọ́ bá dá lẹ́bi yóò san án ni ìlọ́po méjì padà fún ẹnìkejì rẹ̀.
Exodus 22:9 in English
Exodus 22:9 · Berean Standard Bible
In all cases of illegal possession of an ox, a donkey, a sheep, a garment, or any lost item that someone claims, ‘This is mine,’ both parties shall bring their cases before the judges. The one whom the judges find guilty * must pay back double to his neighbor.
Context
7“Bí ọkùnrin kan bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní fàdákà tàbí ohun èlò fún ìtọ́jú, ti wọ́n sì jí gbé lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí a bá mú irú olè bẹ́ẹ̀, yóò san án padà ní ìlọ́po méjì. 8Ṣùgbọ́n ti a kò bá rí olè náà mú, baálé ilé náà yóò fi ara hàn níwájú ìdájọ́ láti jẹ́ kí a mọ̀ bí òun fúnra rẹ̀ ni ó gbé ohun ti ó sọnù náà. 9Bí ẹnìkan bá ni akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, aṣọ tàbí ohun ìní mìíràn tí ó sọnù ní ọ̀nà ti kò bá òfin mu, tí a sì rí ẹni ti ó sọ pé òun ni ó ní ín, àwọn méjèèjì yóò mú ẹjọ́ wọn wá sí iwájú adájọ́. Ẹnikẹ́ni tí adájọ́ bá dá lẹ́bi yóò san án ni ìlọ́po méjì padà fún ẹnìkejì rẹ̀. 10“Bí ẹnikẹ́ni bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, akọ màlúù, àgùntàn tàbí ẹranko mìíràn láti bá òun tọ́jú rẹ̀, tí ó sì kú, tàbí tí ó fi ara pa, tàbí tí a jí gbé, níbi tí kò ti sí ẹni tí o ṣe àkíyèsí. 11Wọn yóò búra sí ọ̀rọ̀ náà láàrín ara wọn ni iwájú Olúwa láti fihàn pé òun kò ní ọwọ́ nínú sísọnù ohun ọ̀sìn náà, olóhun gbọdọ̀ gba bẹ́ẹ̀, a kò sì ní san ohunkóhun fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.