Eksodu 21:8
Exodus 21:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí òun kò bá sì tẹ́ olówó rẹ̀ lọ́rùn, ẹni tí ó fẹ́ ẹ fún ara rẹ̀, yóò jẹ́ kí wọn ó rà á padà, òun kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á bí ẹrú fún àjèjì, nítorí pé òun ni kò ṣe ojúṣe rẹ̀ pẹ̀lú ìwẹ̀fà náà.
Exodus 21:8 in English
Exodus 21:8 · Berean Standard Bible
If she is displeasing in the eyes of her master who had designated her for himself,* he must allow her to be redeemed. He has no right to sell her to foreigners, since he has broken faith with her.
Context
6nígbà náà ni olúwa rẹ̀ yóò mu wá sí iwájú ìdájọ́. Òun yóò sì mú un lọ sí ẹnu-ọ̀nà tàbí lọ sí ibi ọ̀wọ̀n, yóò sì fi ìlu lu etí rẹ̀, òun yóò sì máa sin olówó rẹ̀ títí ayé. 7“Bí ọkùnrin kan bá ta ọmọbìnrin rẹ̀ bí ìwẹ̀fà, ọmọbìnrin yìí kò ní gba òmìnira bí i ti ọmọkùnrin. 8Bí òun kò bá sì tẹ́ olówó rẹ̀ lọ́rùn, ẹni tí ó fẹ́ ẹ fún ara rẹ̀, yóò jẹ́ kí wọn ó rà á padà, òun kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á bí ẹrú fún àjèjì, nítorí pé òun ni kò ṣe ojúṣe rẹ̀ pẹ̀lú ìwẹ̀fà náà. 9Bí ó bá fẹ́ ẹ fún ọmọkùnrin rẹ̀, kò ní máa lò ó bí ìwẹ̀fà mọ́, ṣùgbọ́n yóò máa ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ obìnrin. 10Bí ó bá fẹ́ obìnrin mìíràn, kò gbọdọ̀ kùnà ojúṣe rẹ̀ nípa fífún un ní oúnjẹ àti aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ kùnà ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ sí aya.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.