Eksodu 21:26
Exodus 21:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Bí ọkùnrin kan bá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ní ojú, ti ojú náà sì fọ́, ó ni láti jẹ́ kí ẹrú náà lọ ní òmìnira fún ìtánràn ojú rẹ̀ ti ó fọ́.
Exodus 21:26 in English
Exodus 21:26 · Berean Standard Bible
If a man strikes and blinds the eye of his manservant or maidservant, he must let the servant go free as compensation for the eye.
Context
24Ojú fún ojú, eyín fún eyín, ọwọ́ fún ọwọ́, ẹsẹ̀ fún ẹsẹ̀, 25ìjóná fún ìjóná, ọgbẹ́ fún ọgbẹ́, ìnà fún ìnà. 26“Bí ọkùnrin kan bá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ní ojú, ti ojú náà sì fọ́, ó ni láti jẹ́ kí ẹrú náà lọ ní òmìnira fún ìtánràn ojú rẹ̀ ti ó fọ́. 27Bí ó bá sì lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ti eyín rẹ̀ fi ká, ó ni láti jẹ́ kí ó lọ ní òmìnira ni ìtánràn fún eyín rẹ̀ tí ó ká. 28“Bí akọ màlúù bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin kan pa, a ó sọ akọ màlúù náà ní òkúta pa, a kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀. Ṣùgbọ́n a kò ní dá ẹni tí ó ni akọ màlúù náà lẹ́bi, ọrùn oní akọ màlúù náà yóò sì mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.