Native Bible

Exodus 21:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Bí àwọn ọkùnrin méjì bá ń jà, ti ọ̀kan sọ òkúta tàbí fi ìkùùkuu lu ẹnìkejì rẹ̀, tí ó sì pa á lára, ti irú ìpalára bẹ́ẹ̀ mu kí ó wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn.

Exodus 21:18 in English

Exodus 21:18 · Berean Standard Bible

If men are quarreling and one strikes the other with a stone or a fist, and he does not die but is confined to bed,

Context

16“Ẹnikẹ́ni ti ó bá jí ènìyàn gbé, tí ó sì tà á tàbí tí ó fi pamọ́, pípa ni a ó pa á. 17“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á. 18“Bí àwọn ọkùnrin méjì bá ń jà, ti ọ̀kan sọ òkúta tàbí fi ìkùùkuu lu ẹnìkejì rẹ̀, tí ó sì pa á lára, ti irú ìpalára bẹ́ẹ̀ mu kí ó wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn. 19Ẹni tó lu ẹnìkejì rẹ̀ kò ní ní ẹ̀bi, níwọ̀n ìgbà ti ẹni tí a lù bá ti lè dìde, tí ó sì lé è fi ọ̀pá ìtìlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ rìn káàkiri. Ẹni náà ni láti san owó ti ó fi tọ́jú ara rẹ̀ padà fún un, lẹ́yìn ìgbà tí ara rẹ̀ bá ti yá tan pátápátá. 20“Bí ọkùnrin kan bá fi ọ̀pá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀, ti ẹrú náà sì kú lójú ẹsẹ̀, a ó fi ìyà jẹ ẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.