Native Bible

Exodus 20:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ kò gbọdọ̀ gun àkàsọ̀ lọ sí ibi pẹpẹ mi, kí àwọn ènìyàn má ba à máa wo ìhòhò rẹ láti abẹ́ aṣọ tí ìwọ wọ̀ nígbà tí ìwọ bá ń gòkè lọ sí ibi pẹpẹ.’

Exodus 20:26 in English

Exodus 20:26 · Berean Standard Bible

And you must not go up to My altar on steps, lest your nakedness be exposed on it.’

Context

24“ ‘Pẹpẹ erùpẹ̀ ni kí ìwọ mọ fún mi. Ní orí pẹpẹ yìí ni kí ìwọ ti máa rú ẹbọ sísun rẹ sí mi àti ẹbọ àlàáfíà rẹ, àgùntàn rẹ, ewúrẹ́ àti akọ màlúù rẹ. Ní ibi gbogbo tí mo gbé fi ìrántí orúkọ mi sí, èmi yóò sì máa tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bùkún ọ níbẹ̀. 25Bí ìwọ bá ṣe pẹpẹ òkúta fún mi, má ṣe fi òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ kọ́ ọ, nítorí bí ìwọ bá lo ohun ọnà rẹ lórí rẹ̀, ìwọ sọ ọ di àìmọ́. 26Ìwọ kò gbọdọ̀ gun àkàsọ̀ lọ sí ibi pẹpẹ mi, kí àwọn ènìyàn má ba à máa wo ìhòhò rẹ láti abẹ́ aṣọ tí ìwọ wọ̀ nígbà tí ìwọ bá ń gòkè lọ sí ibi pẹpẹ.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.