Native Bible

Exodus 20:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli, ‘Ẹ̀yin ti rí i fúnra yín bí èmi ti bá a yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá.

Exodus 20:22 in English

Exodus 20:22 · Berean Standard Bible

Then the LORD said to Moses, “This is what you are to tell the Israelites: ‘You have seen for yourselves that I have spoken to you from heaven.

Context

20Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣẹ̀.” 21Àwọn ènìyàn sì dúró ní òkèèrè nígbà tí Mose súnmọ́ ibi òkùnkùn biribiri níbi tí Ọlọ́run wà. 22Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli, ‘Ẹ̀yin ti rí i fúnra yín bí èmi ti bá a yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá. 23Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sin ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi: ẹ̀yin kò gbọdọ̀ rọ ọlọ́run fàdákà tàbí ọlọ́run wúrà fún ara yín. 24“ ‘Pẹpẹ erùpẹ̀ ni kí ìwọ mọ fún mi. Ní orí pẹpẹ yìí ni kí ìwọ ti máa rú ẹbọ sísun rẹ sí mi àti ẹbọ àlàáfíà rẹ, àgùntàn rẹ, ewúrẹ́ àti akọ màlúù rẹ. Ní ibi gbogbo tí mo gbé fi ìrántí orúkọ mi sí, èmi yóò sì máa tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bùkún ọ níbẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.