Eksodu 20:18
Exodus 20:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n ṣìgàṣìgà fún ìbẹ̀rù.
Exodus 20:18 in English
Exodus 20:18 · Berean Standard Bible
When all the people witnessed the thunder and lightning, the sounding of the ram’s horn, and the mountain enveloped in smoke, they trembled and stood at a distance.
Context
16Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ. 17Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéjì rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéjì rẹ.” 18Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n ṣìgàṣìgà fún ìbẹ̀rù. 19Wọ́n wí fún Mose pé, “Ìwọ fúnra rẹ̀ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.” 20Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.