Eksodu 2:21
Exodus 2:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ẹni tí o fi Sippora, ọmọbìnrin rẹ̀ fún Mose láti fi ṣe aya.
Exodus 2:21 in English
Exodus 2:21 · Berean Standard Bible
Moses agreed to stay with the man, and he gave his daughter Zipporah to Moses in marriage.
Context
19Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará Ejibiti kan ni ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn darandaran, ó tilẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti fa omi àti láti fún agbo ẹran ní omi.” 20Ó sọ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, “Níbo ni ó wà? Èéṣe ti ẹ fi fi ọkùnrin náà sílẹ̀? Ẹ pè é wá jẹun.” 21Mose gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ẹni tí o fi Sippora, ọmọbìnrin rẹ̀ fún Mose láti fi ṣe aya. 22Ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Gerṣomu, ó wí pé, “Èmi ń ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.” 23Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ọba Ejibiti kú. Àwọn ará Israẹli ń kérora ní oko ẹrú wọn, wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́ nítorí oko ẹrú tí wọ́n wà, igbe wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.