Native Bible

Exodus 2:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Mose ti dàgbà, ó jáde lọ sí ibi ti àwọn ènìyàn rẹ̀ wà, ó ń wò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ líle wọn, ó ri ará Ejibiti tí ń lu ará Heberu, ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.

Exodus 2:11 in English

Exodus 2:11 · Berean Standard Bible

One day, after Moses had grown up, he went out to his own people * and observed their hard labor. He saw an Egyptian beating a Hebrew, one of his own people.

Context

9Ọmọbìnrin Farao sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ.” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀. 10Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Farao wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mose, ó wí pé, “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.” 11Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Mose ti dàgbà, ó jáde lọ sí ibi ti àwọn ènìyàn rẹ̀ wà, ó ń wò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ líle wọn, ó ri ará Ejibiti tí ń lu ará Heberu, ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. 12Ó wo ìhín, ó wo ọ̀hún, nígbà tí kò rí ẹnìkankan, ni ó bá pa ará Ejibiti náà, ó sì bò ó mọ́ inú iyanrìn. 13Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Heberu méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Heberu arákùnrin rẹ?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.