Eksodu 19:12
Exodus 19:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ìwọ kí ó ṣe ààlà fún àwọn ènìyàn, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ kíyèsí ara yín, kí ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ má tilẹ̀ fi ọwọ́ ba etí rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà, ó dájú, pípa ni a ó pa á.
Exodus 19:12 in English
Exodus 19:12 · Berean Standard Bible
And you are to set up a boundary for the people around the mountain and tell them, ‘Be careful not to go up on the mountain or touch its base. Whoever touches the mountain shall surely be put to death.
Context
10Olúwa sì wí fún Mose pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn. 11Kí wọn kí ó sì múra di ọjọ́ kẹta, nítorí ni ọjọ́ náà ni Olúwa yóò sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai ni ojú gbogbo àwọn ènìyàn. 12Kí ìwọ kí ó ṣe ààlà fún àwọn ènìyàn, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ kíyèsí ara yín, kí ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ má tilẹ̀ fi ọwọ́ ba etí rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà, ó dájú, pípa ni a ó pa á. 13A ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta á ní ọfà, ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án. Ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko, òun kì yóò wà láààyè.’ Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá.” 14Mose sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.