Native Bible

Exodus 18:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì. Orúkọ àkọ́bí ń jẹ́ Gerṣomu; nítorí Mose wí pé, “Èmi ń ṣe àlejò ni ilẹ̀ àjèjì.”

Exodus 18:3 in English

Exodus 18:3 · Berean Standard Bible

along with her two sons. One son was named Gershom,* for Moses had said, “I have been a foreigner in a foreign land.”

Context

1Jetro, àlùfáà Midiani, àna Mose, gbọ́ gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún Mose àti fún Israẹli àwọn ènìyàn rẹ̀, àti bí Olúwa ti mú àwọn ènìyàn Israẹli jáde láti Ejibiti wá. 2Nígbà náà ni Jetro mu aya Mose tí í ṣe Sippora padà lọ sọ́dọ̀ rẹ (nítorí ó ti dá a padà sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ tẹ́lẹ̀), 3Òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì. Orúkọ àkọ́bí ń jẹ́ Gerṣomu; nítorí Mose wí pé, “Èmi ń ṣe àlejò ni ilẹ̀ àjèjì.” 4Èkejì ń jẹ́ Elieseri; ó wí pé, “Ọlọ́run baba mi ni alátìlẹ́yìn mi, ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ idà Farao.” 5Jetro, àna Mose, òun àti aya àti àwọn ọmọ Mose tọ̀ ọ́ wá nínú aginjù tí ó tẹ̀dó sí, nítòsí òkè Ọlọ́run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.