Eksodu 18:25
Exodus 18:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n kún ojú òsùwọ̀n nínú gbogbo Israẹli; ó sì fi wọ́n jẹ olórí àwọn ènìyàn, olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá.
Exodus 18:25 in English
Exodus 18:25 · Berean Standard Bible
So Moses chose capable men from all Israel and made them heads over the people as leaders of thousands, of hundreds, of fifties, and of tens.
Context
23Bí ìwọ bá ṣe èyí, bí Ọlọ́run bá sì fi àṣẹ sí i fún ọ bẹ́ẹ̀, àárẹ̀ kò sì ní tètè mu ọ, àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò sì padà lọ ilé wọn ni àlàáfíà.” 24Mose fetísílẹ̀ sí àna rẹ̀, ó sì ṣe ohun gbogbo tí ó wí fún un. 25Mose sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n kún ojú òsùwọ̀n nínú gbogbo Israẹli; ó sì fi wọ́n jẹ olórí àwọn ènìyàn, olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá. 26Wọ́n sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ní ìgbà gbogbo. Wọ́n sì ń mú ẹjọ́ tó le tọ Mose wá; ṣùgbọ́n wọ́n ń dá ẹjọ́ tí kò le fúnra wọn. 27Mose sì jẹ́ kí àna rẹ̀ lọ ní ọ̀nà rẹ̀, Jetro sì padà sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.