Native Bible

Exodus 17:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Joṣua ṣe bí Mose ti wí fún un, ó sì bá àwọn ará Amaleki jagun; nígbà tí Mose, Aaroni àti Huri lọ sí orí òkè náà.

Exodus 17:10 in English

Exodus 17:10 · Berean Standard Bible

Joshua did as Moses had instructed him and fought against the Amalekites, while Moses, Aaron, and Hur went up to the top of the hill.

Context

8Àwọn ara Amaleki jáde, wọ́n sì dìde ogun sí àwọn ọmọ Israẹli ni Refidimu. 9Mose sì sọ fún Joṣua pé, “Yàn lára àwọn ọkùnrin fún wa, kí wọn ó sì jáde lọ bá àwọn ará Amaleki jà. Ní ọ̀la, èmi yóò dúró ni orí òkè pẹ̀lú ọ̀pá Ọlọ́run ní ọwọ́ mi.” 10Joṣua ṣe bí Mose ti wí fún un, ó sì bá àwọn ará Amaleki jagun; nígbà tí Mose, Aaroni àti Huri lọ sí orí òkè náà. 11Níwọ́n ìgbà tí Mose bá gbé apá rẹ̀ sókè, Israẹli n borí ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá sì rẹ apá rẹ̀ sílẹ̀, Amaleki a sì borí. 12Ṣùgbọ́n apá ń ro Mose, wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà; Aaroni àti Huri sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì; apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti oòrùn wọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.