Native Bible

Exodus 16:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wò ó? Olúwa ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni oúnjẹ ọjọ́ méjì; kí ẹnìkọ̀ọ̀kan dúró ni ibi tí ó gbé wà; kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje.”

Exodus 16:29 in English

Exodus 16:29 · Berean Standard Bible

Understand that the LORD has given you the Sabbath; that is why on the sixth day He will give you bread for two days. On the seventh day, everyone must stay where he is; no one may leave his place.”

Context

27Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ènìyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò ri nǹkan kan kó. 28Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Yóò ti pẹ́ tó ti ẹ ó kọ̀ láti pa àṣẹ mi àti ìlànà mi mọ́? 29Wò ó? Olúwa ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni oúnjẹ ọjọ́ méjì; kí ẹnìkọ̀ọ̀kan dúró ni ibi tí ó gbé wà; kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje.” 30Nítorí náà, àwọn ènìyàn sinmi ní ọjọ́ keje. 31Àwọn ènìyàn Israẹli sì pe oúnjẹ náà ní manna. Ó funfun bí irúgbìn korianderi, ó sì dùn bí àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ti a fi oyin ṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.