Eksodu 16:26
Exodus 16:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi kó o, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ keje ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí i fún un yín ni ọjọ́ náà.”
Exodus 16:26 in English
Exodus 16:26 · Berean Standard Bible
For six days you may gather, but on the seventh day, the Sabbath, it will not be there.”
Context
24Wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ di òwúrọ̀ bí Mose ti pàṣẹ; kò sì rùn bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní ìdin. 25Mose sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ ẹ́ ní òní nítorí òní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi Olúwa. Ẹ̀yin kò ni rí i ni orí ilẹ̀ ní ọjọ́ òní. 26Ní ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi kó o, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ keje ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí i fún un yín ni ọjọ́ náà.” 27Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ènìyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò ri nǹkan kan kó. 28Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Yóò ti pẹ́ tó ti ẹ ó kọ̀ láti pa àṣẹ mi àti ìlànà mi mọ́?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.