Eksodu 15:8
Exodus 15:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ń wọ́jọ pọ̀. Ìṣàn omi dìde dúró bí odi; ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun.
Exodus 15:8 in English
Exodus 15:8 · Berean Standard Bible
At the blast of Your nostrils the waters piled up; like a wall the currents stood firm; the depths congealed in the heart of the sea.
Context
6“Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,
pọ̀ ní agbára.
Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,
fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú. 7“Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi
ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú.
Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ;
tí ó run wọ́n bí àgémọ́lẹ̀ ìdí koríko. 8Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni
omi fi ń wọ́jọ pọ̀.
Ìṣàn omi dìde dúró bí odi;
ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun. 9Ọ̀tá ń gbéraga, ó ń wí pé,
‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn.
èmi ó pín ìkógun;
èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn.
Èmi yóò fa idà mi yọ,
ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’ 10Ìwọ fẹ́ èémí rẹ,
òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀.
Wọ́n rì bí òjé
ni àárín omi ńlá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.