Eksodu 14:27
Exodus 14:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose sì na ọwọ́ rẹ̀ sí orí òkun, òkun sì padà bọ́ sí ipò rẹ̀ nígbà ti ilẹ̀ mọ́. Àwọn ará Ejibiti ń sá fún omi òkun, Olúwa sì gbá wọn sínú òkun.
Exodus 14:27 in English
Exodus 14:27 · Berean Standard Bible
So Moses stretched out his hand over the sea, and at daybreak the sea returned to its normal state. As the Egyptians were retreating, the LORD swept them into the sea.
Context
25Ó sì yọ àgbá ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn kí ó bá à le ṣòro fún wọn láti fi kẹ̀kẹ́ ogun náà rìn. Àwọn ará Ejibiti wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá àsálà kúrò ní iwájú àwọn ará Israẹli nítorí Olúwa ń bá wa jà nítorí wọn.” 26Olúwa sì wí fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sí orí òkun kí omi òkun lè ya padà sórí àwọn ará Ejibiti, kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti sórí ẹlẹ́ṣin wọn.” 27Mose sì na ọwọ́ rẹ̀ sí orí òkun, òkun sì padà bọ́ sí ipò rẹ̀ nígbà ti ilẹ̀ mọ́. Àwọn ará Ejibiti ń sá fún omi òkun, Olúwa sì gbá wọn sínú òkun. 28Omi òkun sì ya padà, ó sì bo kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin: àní, gbogbo ọmọ-ogun Farao tiwọn wọ inú òkun tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yè. 29Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli la òkun kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ pẹ̀lú ògiri omi ni ọ̀tún àti òsì wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.