Native Bible

Exodus 14:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni angẹli Ọlọ́run tó ti ń ṣáájú ogun Israẹli lọ, padà o sì rìn ni ẹ̀yìn wọn; Òpó ìkùùkuu tí ń rìn ni iwájú wọn sì padà sí í rìn ni ẹ̀yìn wọn.

Exodus 14:19 in English

Exodus 14:19 · Berean Standard Bible

And the angel * of God, who had gone before the camp of Israel, withdrew and went behind them. The pillar of cloud also moved from before them and stood behind them,

Context

17Nígbà náà ni èmi yóò sé ọkàn àwọn ará Ejibiti le, wọn yóò sì máa lépa wọn; Èmi yóò gba ògo fún ara mi lórí Farao; lórí gbogbo ogun rẹ̀, lórí kẹ̀kẹ́ ogun àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. 18Àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa nígbà ti èmi bá gba ògo fún ara mi lórí Farao: lórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.” 19Nígbà náà ni angẹli Ọlọ́run tó ti ń ṣáájú ogun Israẹli lọ, padà o sì rìn ni ẹ̀yìn wọn; Òpó ìkùùkuu tí ń rìn ni iwájú wọn sì padà sí í rìn ni ẹ̀yìn wọn. 20Ó sì wà láàrín àwọn ọmọ-ogun Ejibiti àti Israẹli. Ìkùùkuu sì ṣú òkùnkùn sí àwọn ará Ejibiti ni òru náà. Ṣùgbọ́n ó tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn Israẹli ni òru náà, ọ̀kan kò sì súnmọ́ èkejì ni gbogbo òru náà. 21Nígbà náà ni Mose na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, ni gbogbo òru náà ni Olúwa fi lé òkun sẹ́yìn pẹ̀lú ìjì líle láti ìlà-oòrùn wá, ó sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀. Omi òkun sì pínyà,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.