Eksodu 14:10
Exodus 14:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí Farao ti súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú wọn sókè, wọn sì rí àwọn ará Ejibiti tó súnmọ́ wọn. Ẹ̀rù ńlá sì bá àwọn ará Israẹli, wọ́n kígbe sókè sí Olúwa.
Exodus 14:10 in English
Exodus 14:10 · Berean Standard Bible
As Pharaoh approached, the Israelites looked up and saw the Egyptians marching after them, and they were terrified and cried out to the LORD.
Context
8Olúwa sé ọkàn Farao ọba Ejibiti le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Israẹli ti ń jáde lọ ní àìbẹ̀rù. 9Àwọn ará Ejibiti ń lépa wọn pẹ̀lú gbogbo ẹṣin kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, wọ́n sì lé wọn bá ni ibi tí wọ́n pa àgọ́ sí lẹ́bàá òkun ní ìhà Pi-Hahirotu, ni òdìkejì Baali-Ṣefoni. 10Bí Farao ti súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú wọn sókè, wọn sì rí àwọn ará Ejibiti tó súnmọ́ wọn. Ẹ̀rù ńlá sì bá àwọn ará Israẹli, wọ́n kígbe sókè sí Olúwa. 11Wọ́n sọ fún Mose pé, “Ṣe nítorí pé kò sí ibojì ni Ejibiti ní ìwọ ṣe mú wa wá láti kú sínú aginjù? Kí ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa ti ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti wá? 12Ǹjẹ́ èyí kọ́ ni àwa sọ fún ọ ni Ejibiti, ‘Fi wá sílẹ̀, jẹ́ kí àwa máa sin ará Ejibiti’? Nítorí kò bá sàn fún wa kí a sin àwọn ará Ejibiti ju kí a kú sínú aginjù yìí lọ!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.