Native Bible

Exodus 13:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Yóò sí ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín yóò béèrè lọ́wọ́ yín, ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ Kí ìwọ kí ó sọ fún wọn pé, ‘Pẹ̀lú ọwọ́ agbára ní Olúwa fi mú wa jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní oko ẹrú.

Exodus 13:14 in English

Exodus 13:14 · Berean Standard Bible

In the future, when your son asks you, ‘What does this mean?’ you are to tell him, ‘With a mighty hand the LORD brought us out of Egypt, out of the house of slavery.

Context

12ìwọ yóò fi àkọ́bí inú rẹ fún Olúwa. Gbogbo àkọ́bí ti ó jẹ́ akọ ti ẹran ọ̀sìn rẹ ní ó jẹ́ ti Olúwa. 13Ìwọ yóò fi ọ̀dọ́-àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, ǹjẹ́ kí ìwọ ṣẹ́ ẹ ní ọrùn, gbogbo àkọ́bí ọkùnrin ni kí ìwọ kí ó rà padà. 14“Yóò sí ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín yóò béèrè lọ́wọ́ yín, ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ Kí ìwọ kí ó sọ fún wọn pé, ‘Pẹ̀lú ọwọ́ agbára ní Olúwa fi mú wa jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní oko ẹrú. 15Ní ìgbà ti Farao ṣe orí kunkun, ti ó kọ̀ láti jẹ́ kí a lọ, Olúwa pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, àti ènìyàn àti ẹranko. Ìdí èyí ni àwa fi ń fi gbogbo àkọ́bí tí í ṣe akọ rú ẹbọ sí Olúwa láti fi ṣe ìràpadà fún àwọn àkọ́bí wa ọkùnrin.’ 16Èyí yóò sì jẹ́ àmì ni ọwọ́ yín àti àmì ní iwájú orí yín pé Olúwa mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.