Native Bible

Exodus 12:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ìdílé kan bá kéré jù fún odidi ọ̀dọ́-àgùntàn kan, kí wọn kí ó ṣe àjọpín ọ̀kan pẹ̀lú aládùúgbò wọn ti ó sun mọ́ wọn kí wọ́n lo iye ènìyàn tiwọn jẹ láti ṣe òdínwọ̀n irú ọ̀dọ́-àgùntàn tiwọn yóò lò ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀n ti ẹni kọ̀ọ̀kan lè jẹ.

Exodus 12:4 in English

Exodus 12:4 · Berean Standard Bible

If the household is too small for a whole lamb, they are to share with the nearest neighbor based on the number of people, and apportion the lamb accordingly.

Context

2“Oṣù yìí ni yóò jẹ́ oṣù àkọ́kọ́ fún yín, oṣù àkọ́kọ́ nínú ọdún yín. 3Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli pé ni ọjọ́ kẹwàá oṣù yìí, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan yóò mú ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan fún ìdílé rẹ̀, ọ̀kan fún agbo ilé kọ̀ọ̀kan. 4Bí ìdílé kan bá kéré jù fún odidi ọ̀dọ́-àgùntàn kan, kí wọn kí ó ṣe àjọpín ọ̀kan pẹ̀lú aládùúgbò wọn ti ó sun mọ́ wọn kí wọ́n lo iye ènìyàn tiwọn jẹ láti ṣe òdínwọ̀n irú ọ̀dọ́-àgùntàn tiwọn yóò lò ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀n ti ẹni kọ̀ọ̀kan lè jẹ. 5Ọ̀dọ́-àgùntàn tí ìwọ yóò mú gbọdọ̀ jẹ́ akọ ọlọ́dún kan tí kò lábùkù, ìwọ lè mú lára àgbò tàbí ewúrẹ́. 6Ṣe ìtọ́jú wọn títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli yóò pa ẹran náà ní àfẹ̀mọ́júmọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.