Native Bible

Exodus 12:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọ̀gànjọ́ òru Olúwa kọlu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, láti orí àkọ́bí. Farao tí ó wà ní orí ìtẹ́ títí dé orí àkọ́bí ẹlẹ́wọ̀n tí ó wà nínú túbú àti àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú.

Exodus 12:29 in English

Exodus 12:29 · Berean Standard Bible

Now at midnight the LORD struck down every firstborn male in the land of Egypt, from the firstborn of Pharaoh, who sat on his throne, to the firstborn of the prisoner in the dungeon, as well as all the firstborn among the livestock.

Context

27Ẹ sọ fún wọn ni ìgbà náà, ‘Ẹbọ ìrékọjá sí Olúwa ni, ẹni tí ó rékọjá ilé àwọn ọmọ Israẹli ni ìgbà tí ó kọlu àwọn ara Ejibiti. Tí ó si da wa sí nígbà ti ó pa àwọn ara Ejibiti.’ ” Àwọn ènìyàn sì tẹríba láti sìn. 28Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose àti Aaroni. 29Ní ọ̀gànjọ́ òru Olúwa kọlu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, láti orí àkọ́bí. Farao tí ó wà ní orí ìtẹ́ títí dé orí àkọ́bí ẹlẹ́wọ̀n tí ó wà nínú túbú àti àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú. 30Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn ara Ejibiti dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, igbe ẹkún ńlá sì gba gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, nítorí kò sí ilé kan tí ó yọ sílẹ̀ tí ènìyàn kan kò ti kú. 31Farao sì ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni ní òru, ó sì wí pé, “Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin àti àwọn ènìyàn Israẹli! Ẹ lọ láti sin Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹ ti béèrè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.