Native Bible

Exodus 12:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fún ọjọ́ méje ni ẹ kò gbọdọ̀ ni ìwúkàrà nínú ilé yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó ni ìwúkàrà nínú ni a ó yọ kúrò ni àárín àwùjọ Israẹli, ìbá à ṣe àlejò tàbí ẹni tí a bí ní ilẹ̀ náà.

Exodus 12:19 in English

Exodus 12:19 · Berean Standard Bible

For seven days there must be no leaven found in your houses. If anyone eats something leavened, that person, whether a foreigner or native of the land, must be cut off from the congregation of Israel.

Context

17“Ẹ ó sì kíyèsí àjọ àìwúkàrà, nítorí ní ọjọ́ náà gan an ni mo mú ogun yín jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. Nítorí náà ni kí ẹ máa kíyèsi ọjọ́ náà ní ìran-ìran yín bí ìlànà tí yóò wà títí ayé. 18Àkàrà ti kò ni ìwúkàrà ni ẹ̀yin yóò jẹ láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀kànlélógún oṣù àkọ́kọ́. 19Fún ọjọ́ méje ni ẹ kò gbọdọ̀ ni ìwúkàrà nínú ilé yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó ni ìwúkàrà nínú ni a ó yọ kúrò ni àárín àwùjọ Israẹli, ìbá à ṣe àlejò tàbí ẹni tí a bí ní ilẹ̀ náà. 20Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe. Ní ibikíbi tí ẹ̀yin bá ń gbé, kí ẹ̀yin kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.” 21Ní ìgbà náà ni Mose pé gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ jáde lọ, kí ẹ sì yan ọ̀dọ́-àgùntàn fún àwọn ìdílé yín, kí ẹ sì pa ẹran àjọ ìrékọjá Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.