Eksodu 11:4
Exodus 11:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Mose wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ‘Ní ọ̀gànjọ́ òru èmi yóò la ilẹ̀ Ejibiti kọjá.
Exodus 11:4 in English
Exodus 11:4 · Berean Standard Bible
So Moses declared, “This is what the LORD says: ‘About midnight I will go throughout Egypt,
Context
2Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé kí tọkùnrin tobìnrin wọn béèrè fún ohun èlò fàdákà àti wúrà lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀. 3(Olúwa jẹ́ kí wọn rí ojúrere àwọn ará Ejibiti, pàápàá, Mose fúnra rẹ̀ di ènìyàn pàtàkì ní ilẹ̀ Ejibiti ní iwájú àwọn ìjòyè Farao àti ní iwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú). 4Nígbà náà ni Mose wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ‘Ní ọ̀gànjọ́ òru èmi yóò la ilẹ̀ Ejibiti kọjá. 5Gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti ni yóò kùú, bẹ̀rẹ̀ lórí àkọ́bí ọkùnrin Farao tí ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, tí ó fi dé orí àkọ́bí ọmọkùnrin ti ẹrúbìnrin tí ń lọ ọlọ àti gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú. 6Igbe ẹkún ńlá yóò sọ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Irú ohun búburú tí kò ṣẹlẹ̀ rí tí kò sí tún ni ṣẹlẹ̀ mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.