Eksodu 10:6
Exodus 10:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn yóò kún gbogbo ilé rẹ àti ilé àwọn ìjòyè rẹ àti ilé gbogbo àwọn ará Ejibiti. Ohun ti baba rẹ tàbí baba baba rẹ kò tí ì rí láti ìgbà tí wọ́n ti wà ní ilẹ̀ náà títí di àkókò yìí.’ ” Nígbà náà ni Mose pẹ̀yìndà kúrò níwájú Farao.
Exodus 10:6 in English
Exodus 10:6 · Berean Standard Bible
They will fill your houses and the houses of all your officials and every Egyptian—something neither your fathers nor your grandfathers have seen since the day they came into this land.’” Then Moses turned and left Pharaoh’s presence.
Context
4Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn lọ, èmi yóò mú eṣú wa sí orílẹ̀-èdè rẹ ní ọ̀la. 5Wọn yóò bo gbogbo ilẹ̀. Wọn yóò ba ohun gbogbo tí ó kù fún ọ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́, tí ó fi dórí gbogbo igi tí ó ń dàgbà ni ilẹ̀ rẹ. 6Wọn yóò kún gbogbo ilé rẹ àti ilé àwọn ìjòyè rẹ àti ilé gbogbo àwọn ará Ejibiti. Ohun ti baba rẹ tàbí baba baba rẹ kò tí ì rí láti ìgbà tí wọ́n ti wà ní ilẹ̀ náà títí di àkókò yìí.’ ” Nígbà náà ni Mose pẹ̀yìndà kúrò níwájú Farao. 7Àwọn ìjòyè Farao sọ fún un, “Yóò ti pẹ́ to tí ọkùnrin yìí yóò máa jẹ́ ìkẹ́kùn fún wa? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí lọ, kí wọn kí ó le sìn Olúwa Ọlọ́run wọn. Ṣe ìwọ kò ṣe àkíyèsí síbẹ̀ pé, ilẹ̀ Ejibiti ti parun tán?” 8Nígbà náà ni a mú Aaroni àti Mose padà wá sí iwájú Farao ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sìn Olúwa Ọlọ́run yín. Ṣùgbọ́n àwọn ta ni nínú yín ni yóò ha lọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.