Eksodu 10:1
Exodus 10:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, mo ti ṣé àyà Farao le àti àyà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kí èmi kí o ba le ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrín wọn.
Exodus 10:1 in English
Exodus 10:1 · Berean Standard Bible
Then the LORD said to Moses, “Go to Pharaoh, for I have hardened * his heart and the hearts of his officials, that I may perform these miraculous signs of Mine among them,
Context
1Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, mo ti ṣé àyà Farao le àti àyà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kí èmi kí o ba le ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrín wọn. 2Kí ẹ̀yin ki ó le sọ fún àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ ọmọ yín; bí mo ti jẹ àwọn ará Ejibiti ní yà àti bí mo ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn. Kí ìwọ ba á le mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.” 3Nígbà náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, tiwọn sí wí fún un pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run àwọn Heberu sọ, ‘Yóò ti pẹ́ to ti ìwọ yóò kọ̀ láti tẹrí ara rẹ ba ní iwájú mi? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó sìn mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.