Native Bible

Exodus 1:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Ejibiti ń lò wọ́n ní ìlòkulò.

Exodus 1:14 in English

Exodus 1:14 · Berean Standard Bible

and made their lives bitter with hard labor in brick and mortar, and with all kinds of work in the fields. Every service they imposed was harsh.

Context

12Ṣùgbọ́n bí a ti ń ni wọ́n lára tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, tí wọ́n sì ń tànkálẹ̀. Nítorí náà, àwọn ará Ejibiti bẹ̀rù nítorí àwọn ará Israẹli. 13Àwọn ará Ejibiti sì mú àwọn ọmọ Israẹli sìn ní àsìnpa. 14Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Ejibiti ń lò wọ́n ní ìlòkulò. 15Ọba Ejibiti sọ fún àwọn agbẹ̀bí Heberu ti orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣifura àti Pua pé, 16“Nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Heberu, tí ẹ sì kíyèsi wọn lórí ìkúnlẹ̀ ìrọbí wọn, bí ó bá jẹ́ ọkùnrin ni ọmọ náà, ẹ pa á; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ obìnrin, ẹ jẹ́ kí ó wà láààyè.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.