Esteri 9:4
Esther 9:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mordekai sì jẹ́ ẹni pàtàkì ní ààfin ọba, òkìkí rẹ̀ sì tàn jákèjádò àwọn ìgbèríko, ó sì ní agbára kún agbára.
Esther 9:4 in English
Esther 9:4 · Berean Standard Bible
For Mordecai exercised great power in the palace, and his fame spread throughout the provinces as he became more and more powerful.
Context
2Àwọn Júù péjọ ní àwọn ìlú u wọn ní gbogbo agbègbè ọba Ahaswerusi láti kọlu àwọn tó ń wá ìparun wọn. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè dojúkọ wọ́n, nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ìlú tókù ń bẹ̀rù u wọn. 3Gbogbo àwọn ọlọ́lá ìgbèríko, àwọn alákòóso, àwọn baálẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ ọba ran àwọn Júù lọ́wọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù u Mordekai. 4Mordekai sì jẹ́ ẹni pàtàkì ní ààfin ọba, òkìkí rẹ̀ sì tàn jákèjádò àwọn ìgbèríko, ó sì ní agbára kún agbára. 5Àwọn Júù sì gé gbogbo àwọn ọ̀tá a wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì run wọ́n, wọ́n sì ṣe ohun tí ó wù wọ́n sí àwọn tí ó kórìíra wọn. 6Ní ilé ìṣọ́ ti Susa, àwọn Júù pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọkùnrin run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.