Esteri 9:16
Esther 9:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lákokò yìí, àwọn tókù nínú àwọn Júù tí wọ́n wà ní agbègbè ọba náà tún kó ara wọn jọ láti dáàbò bo ara wọn kí wọn sì sinmi lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn. Wọ́n sì pa ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀rin (75,000) àwọn tí ó kórìíra wọn ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn.
Esther 9:16 in English
Esther 9:16 · Berean Standard Bible
The rest of the Jews in the royal provinces also assembled to defend themselves and rid themselves of their enemies. They killed 75,000 who hated them, but they did not lay a hand on the plunder.
Context
14Nítorí náà ọba pàṣẹ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. A sì gbé àṣẹ kan jáde ní Susa, wọ́n sì so àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá Hamani kọ́. 15Àwọn Júù tí ó wà ní Susa sì péjọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari, wọ́n sì pa ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin ní Susa, ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn. 16Lákokò yìí, àwọn tókù nínú àwọn Júù tí wọ́n wà ní agbègbè ọba náà tún kó ara wọn jọ láti dáàbò bo ara wọn kí wọn sì sinmi lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn. Wọ́n sì pa ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀rin (75,000) àwọn tí ó kórìíra wọn ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn. 17Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Addari, wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀. 18Àwọn Júù tí ó wà ní Susa, kó ara wọn jọ ní ọjọ́ kẹtàlá àti ọjọ́ kẹrìnlá, nígbà tí ó sì di ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún wọ́n sinmi wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.