Esteri 8:5
Esther 8:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó wí pé, “Bí ó bá wu ọba, tí ó bá sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ojúrere tí ó sì rò pé ohun tí ó dára ni láti ṣe, tí ó bá sì ní inú dídùn pẹ̀lú mi, jẹ́ kí a kọ ìwé àṣẹ láti yí ète tí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, tí ó kọ́ pàṣẹ pé kí a pa àwọn Júù tí wọ́n wà ní gbogbo àgbáyé ìjọba ọba run.
Esther 8:5 in English
Esther 8:5 · Berean Standard Bible
“If it pleases the king,” she said, “and if I have found favor in his sight, and the matter seems proper to the king, and I am pleasing in his sight, may an order be written to revoke the letters that the scheming Haman son of Hammedatha, the Agagite, wrote to destroy the Jews in all the king’s provinces.
Context
3Esteri sì tún bẹ ọba lórí ìkúnlẹ̀, pẹ̀lú omijé lójú. Ó bẹ̀ ẹ́ kí ó fi òpin sí ètò búburú Hamani ará Agagi, èyí tí ó ti pète fún àwọn Júù. 4Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá aládé wúrà sí Esteri ó sì dìde, ó dúró níwájú rẹ̀. 5Ó wí pé, “Bí ó bá wu ọba, tí ó bá sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ojúrere tí ó sì rò pé ohun tí ó dára ni láti ṣe, tí ó bá sì ní inú dídùn pẹ̀lú mi, jẹ́ kí a kọ ìwé àṣẹ láti yí ète tí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, tí ó kọ́ pàṣẹ pé kí a pa àwọn Júù tí wọ́n wà ní gbogbo àgbáyé ìjọba ọba run. 6Nítorí báwo ni èmi yóò ṣe fi ara dà á tí èmi yóò sì rí kí ibi máa ṣubú lu àwọn ènìyàn mi? Báwo ni èmi yóò ṣe fi ara dà á, tí èmi yóò sì máa wo ìparun àwọn ìdílé mi?” 7Ọba Ahaswerusi dá Esteri ayaba àti Mordekai ará a Júù náà lóhùn pé, “Nítorí Hamani kọlu àwọn ará a Júù, èmi ti fi ilé e rẹ̀ fún Esteri, wọ́n sì ti ṣo ó kọ́ sórí igi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.