Native Bible

Esther 8:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mordekai sì kúrò níwájú ọba, ó wọ aṣọ aláró àti funfun, ó dé adé e wúrà ńlá pẹ̀lú ìgbànú elése àlùkò dáradára, ìlú Susa sì ṣe àjọyọ̀ ńlá.

Esther 8:15 in English

Esther 8:15 · Berean Standard Bible

Mordecai went out from the presence of the king in royal garments of blue and white, with a large gold crown and a purple robe of fine linen. And the city of Susa shouted and rejoiced.

Context

13Ọkàn ìwé àṣẹ náà ni kí a gbé jáde gẹ́gẹ́ bí òfin ní gbogbo ìgbèríko kí ẹ sì jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún gbogbo ènìyàn ìlú nítorí àwọn Júù yóò le è múra ní ọjọ́ náà láti gbẹ̀san fún ara wọn lára àwọn ọ̀tá wọn. 14Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ ayaba tiwọn yára bí àṣà tí wọ́n ń gun ẹṣin ọba, sáré jáde, wọ́n sáré lọ nípa àṣẹ ọba. A sì tún gbé àṣẹ náà jáde ní ilé ìṣọ́ ti Susa. 15Mordekai sì kúrò níwájú ọba, ó wọ aṣọ aláró àti funfun, ó dé adé e wúrà ńlá pẹ̀lú ìgbànú elése àlùkò dáradára, ìlú Susa sì ṣe àjọyọ̀ ńlá. 16Àsìkò ìdùnnú àti ayọ̀, inú dídùn àti ọlá ni ó jẹ́ fún àwọn Júù. 17Ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú, ní gbogbo ibi tí àṣẹ ọba dé, ni ayọ̀ àti inú dídùn ti wà láàrín àwọn Júù, wọ́n sì ń ṣe àsè àti àjọyọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú tókù sọ ara wọn di Júù nítorí ẹ̀rù àwọn Júù bà wọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.