Native Bible

Esther 8:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àṣẹ ọba sì dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní gbogbo ìlú láti kó ara wọn jọ kí wọn sì dáàbò bo ara wọn; láti pa, láti run àti láti kọlu ogunkógun orílẹ̀-èdè kórílẹ̀ èdè kankan tàbí ìgbèríko tí ó bá fẹ́ kọlù wọ́n, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn; kí ẹ sì kó gbogbo ohun ìní àwọn ọ̀tá wọn.

Esther 8:11 in English

Esther 8:11 · Berean Standard Bible

By these letters the king permitted the Jews in each and every city the right to assemble and defend themselves, to destroy, kill, and annihilate all the forces of any people or province hostile to them, including women and children, and to plunder their possessions.

Context

9Lẹ́sẹ̀kan náà àwọn akọ̀wé ọba péjọ ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta, oṣù Sifani. Wọ́n kọ gbogbo àṣẹ Mordekai sí àwọn Júù, àti sí àwọn alákòóso baálẹ̀ àti àwọn ọlọ́lá ìgbèríko mẹ́tàdínláàádóje (127) tí ó lọ láti India títí ó fi dé Kuṣi. Kí a kọ àṣẹ náà ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé àti bí èdè olúkúlùkù àti pẹ̀lú sí àwọn Júù ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé àti èdè e wọn. 10Mordekai sì fi àṣẹ ọba Ahaswerusi kọ̀wé, ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀, ó rán an lọ ní kíákíá, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ ayaba, tiwọn yára bí àṣà àwọn tí wọ́n ń gun ẹṣin tí ó yára, ní pàtàkì èyí tí a ń bọ́ fún ọba. 11Àṣẹ ọba sì dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní gbogbo ìlú láti kó ara wọn jọ kí wọn sì dáàbò bo ara wọn; láti pa, láti run àti láti kọlu ogunkógun orílẹ̀-èdè kórílẹ̀ èdè kankan tàbí ìgbèríko tí ó bá fẹ́ kọlù wọ́n, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn; kí ẹ sì kó gbogbo ohun ìní àwọn ọ̀tá wọn. 12Ọjọ́ tí a yàn fún àwọn Júù ní gbogbo agbègbè ọba Ahaswerusi láti ṣe nǹkan yìí ni ọjọ́ kẹtàlá èyí tí í ṣe oṣù kejìlá, oṣù Addari. 13Ọkàn ìwé àṣẹ náà ni kí a gbé jáde gẹ́gẹ́ bí òfin ní gbogbo ìgbèríko kí ẹ sì jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún gbogbo ènìyàn ìlú nítorí àwọn Júù yóò le è múra ní ọjọ́ náà láti gbẹ̀san fún ara wọn lára àwọn ọ̀tá wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.